1 Olúwa sọ fún Mósè pé;
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi ó fún yin gẹ́gẹ́ bí ibùgbé
3 tí ẹ sì mú ọrẹ àfinásun wá, yálà nínú ọ̀wọ́ ẹran gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, bóyá ọrẹ sísun tàbí ẹbọ sísun, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá,
4 nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná pẹ̀lú ìdásímẹ́rin òṣùwọ̀n òróró wá ṣíwájú Olúwa.
5 Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan yálà fún ọrẹ tabí ẹbọ sísun ni, kí ẹ pèsè ìdá sí mẹ́rin òṣùwọ̀n wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun mímu.
6 “ ‘Fún àgbò kan ni kí ẹ pèsè ọrẹ ohun jíjẹ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n òróró pò.
7 Àti ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n wáìnì fún ọrẹ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.
8 “ ‘Nígbà tí ẹ bá sì pèsè ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ọrẹ tàbí ẹbọ sísun, láti fi san ẹ̀jẹ́ tàbí fún ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa,
9 Ẹni náà yóò mú ọ̀dọ́ akọ màlúù náà wá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, ìdá sí mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ìyẹ̀fun kíkúná tí a fi ìdajì òṣùwọ̀n òróro pò.
10 Kí ó tún mú ìdajì òsùwọ̀n wáìnì wá fún ọrẹ ohun mímu. Yóò jẹ́ ọrẹ àfinásun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
11 Báyìí ni kí ẹ se pèṣè ọ̀dọ́ akọ màlúù tàbí àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí ọmọ ewúrẹ́.
12 Ẹ se bẹ́ẹ̀ fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, iyekíye tí ẹ̀yin ì bá à pèsè.
13 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín ni kí ó máa se àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà tí ó bá mú ọrẹ àfinásun gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn wá fún Olúwa.
14 Bí àléjò kan bá ń gbé láàrin yín ní gbogbo ìran yín, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ mú ọrẹ àfinásun bí òórùn dídùn wá fún Olúwa, gbogbo bí ẹ bá ṣe ń ṣe náà ni kí ó ṣe.
15 Gbogbo ìjọ ènìyàn gbọdọ̀ ní òfin kan náà fún ọmọ bíbí ilẹ̀ yín àti fún àwọn àlejò tó ń gbé láàrin yín, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún àwọn ìran tó ń bọ̀. Ẹ̀yin àti àlejò tó ń gbé láàrin yín sì jẹ́ bákan náà níwájú Olúwa:
16 Òfin kan àti ìlànà kan ni yóò wà fún yín àti fún àwọn àlejò tí ń gbé láàrin yín.’ ”
17 Olúwa sọ fún Mósè pé,
18 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísirẹ́lì pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí mo ń mú yín lọ.
19 Tí ẹ sì jẹ oúnjẹ ilẹ̀ náà, ẹ mú nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè wá fún Olúwa.
20 Ẹ mú àkàrà wá nínú àkọ́so oúnjẹ yín wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ìgbésókè sí Olúwa, ọrẹ láti inú ilẹ̀ ìpakà yín.
21 Nínú àkọ́so oúnjẹ yín ni kí ẹ ti máa mú ọrẹ ìgbésókè yìí fún Olúwa.
22 “ ‘Bí ẹ bá kùnà láìròtẹ́lẹ̀ láti pa àwọn òfin tí Olúwa fún Mósè mọ́:
23 Èyí ni gbogbo òfin tí Olúwa fún yín láti ẹnu Mósè láti ọjọ́ tí Olúwa ti fún yín àti títí dé ìran tó ń bọ̀.
24 Bí ẹ̀ṣẹ̀ bá wáyé láìròtẹ́lẹ̀ láì jẹ́ pé ìjọ ènìyàn mọ̀ sí i, nígbà náà ni kí gbogbo ìjọ ènìyàn mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan wá fún ẹbọ sísun bí òórùn dídùn sí Olúwa, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà, pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
25 Àlùfáà yóò sì se ètùtù, fun gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì, a ó sì dárí jìn wọ́n, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀, wọ́n sì ti mú ọrẹ àfinásun wá fún Olúwa nítori ẹ̀sẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀.
26 A ó dárí ji gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárin wọn nítorí pé ní àìròtẹ́lẹ̀ ni wọ́n sẹ ẹ̀ṣẹ̀ náà.
27 “ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé ẹnìkan ló sẹ̀ ní àìròtẹ́lẹ̀, kí ó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
28 Àlùfáà yóò ṣe ètùtù níwájú Olúwa fún ẹni tó ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, tí wọ́n bá ṣe ètùtù fún un, a ó sì dárí jì í.
29 Òfin kan náà ló wà fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, yálà ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò tí ń gbé láàrin yín.
30 “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá mọ̀-ọ́n-mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ yálà ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ yín tàbí àlejò, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ Olúwa, a ó sì gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀
31 Nítorí pé ẹni náà ti kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa ó sì ti rú òfin rẹ̀, a gbọdọ̀ gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí rẹ̀.’ ”
32 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísirẹ́lì wà nínú ihà, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi ní ọjọ́ Ísínmì.
33 Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣa igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mósè àti Árónì àti ṣíwájú gbogbo ìjọ ènìyàn;
34 Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn.
35 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Kíkú ni ọkùnrín náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sọ ọ́ lókúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.”
36 Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.
37 Olúwa sọ fún Mósè pé,
38 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan.
39 Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wò láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbérè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín.
40 Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́ran láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín.
41 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Éjíbítì láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”