1 Olúwa sọ fún Mósè pé:
2 Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o má a lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín.
3 Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé ṣíwájú rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
4 Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náa ni àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì yóò péjọ ṣíwájú rẹ.
5 Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà oòrùn ni yóò gbéra.
6 Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra.
7 Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má se fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀.
8 “Àwọn Ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀.
9 Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀ta tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì ránti yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta yín.
10 Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ yín àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.”
11 Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùukù kúrò lórí tabánákù Ẹ̀rí.
12 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbéra kúrò ní ihà Sínáì wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùukù fi dúró sí ihà Páránì.
13 Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.
14 Àwọn ìpín ti ibùdó Júdà ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Náṣónì ọmọ Ámínádábù ni ọ̀gágun wọn.
15 Nẹ̀taníẹ́lì ọmọ Ṣúárì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Ísákárì;
16 Élíábù ọmọ Hélónì ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì.
17 Nígbà náà ni wọ́n sọ tabánákù kalẹ̀ àwọn ọmọ Gáṣónì àti Mérárì tó gbé àgọ́ sì gbéra.
18 Àwọn ìpín ti ibùdó ti Rúbẹ́nì ló gbéra tẹ̀le wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Élísúrì ọmọ Sédúrì ni ọ̀gágun wọn.
19 Ṣélúmíélì ọmọ Surisádáì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Símónì.
20 Élíásáfì ọmọ Déúélì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gáádì.
21 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kóhátì tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabánákù dúró kí wọn tó dé.
22 Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Éfúráímù ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisámà ọmọ Ámíhúdì ni ọ̀gágun wọn.
23 Gàmálíélì ọmọ Pédásúrì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Mánásè.
24 Ábídánì ọmọ Gídíónì ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì.
25 Lákòótan, àwọn ọmọ ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dánì lábẹ́ ọ̀págun wọn. Áhíésérì ọmọ Ámíṣádárì ni ọ̀gágun wọn.
26 Págíélì ọmọ Ókíránì ni ìpín ti ẹ̀yà Ásérì,
27 Áhírà ọmọ Énánì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Náfítanì;
28 Báyìí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.
29 Mósè sì sọ fún Hóbábì ọmọ Réúélì ará Mídíánì tí í se àna Mósè pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ àwa ó se ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Ísírẹ́lì.”
30 Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”
31 Mósè sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú ihà, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa.
32 Bí o bá báwa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”
33 Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí Ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn.
34 Ìkúùkù Olúwa wà lórí wọn lọ́sán nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.
35 Nígbàkigbà tí àpótí Ẹ̀rí bá gbéra Mósè yóò sì wí pé;“Dìdé, Olúwa!Kí a tú àwọn ọ̀ta rẹ ká,kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”
36 Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé;“Padà, Olúwa,Sọ́dọ̀ àwọn àìmọye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì.”