Nọ́ḿbà 23 BMY

Ọ̀rọ̀ Ìjìnlẹ̀ Àkọ́kọ́ Bálámù

1 Bálámù sọ́ wí pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.”

2 Bálákì ṣe bí Bálámù ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

3 Nígbà náà Bálámù sọ fún Bálákì pé, “Dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn, mí màá sọ fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.

4 Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Bálámù sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ.”

5 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Bálámù ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.”

6 Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Móábù.

7 Nígbà náà ni Bálámù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ jáde wí pé:“Bálákì mú mi láti Árámù wá,ọba Móábù láti òkè ìlà oòrùn wáÓ wí pé, ‘Wá fi Jákọ́bù bú fún mi;wá, kí o sì jẹ́rì i sí Ísírẹ́lì.’

8 Báwo ní èmi ó ṣe fi búàwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wíàwọn tí Olúwa kò bá wí?

9 Láti ṣónṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀ èdè.

10 Ta ni ó lè ka eruku Jákọ́bùtàbí ka ìdámẹ́rin Ísírẹ́lì?Jẹ́ kí èmi kú ikú olóòtọ́,kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dàbí ti wọn!”

11 Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀ta mi bú, Ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan Ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”

12 Ó sì dáhùn wí pé, “Sé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

Ọ̀rọ̀ Ìjìnlẹ̀ Èkejì Bálámù

13 Nígbà náà Bálákì sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀ Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”

14 Ó sì lọ sí pápá Ṣóímù ní orí òkè Písígà, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

15 Bálámù ṣo fún Bálákì pé, “Dúró níbí ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ.”

16 Olúwa pàdé Bálámù ó sì fí ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Bálákì kí o sì jísẹ́ fún un.”

17 Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì báà tí ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Móábù. Bálákì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”

18 Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ:“Dìde, Bálákì;kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sípórà.

19 Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu-un ṣẹ?

20 Èmi gba àṣẹ láti bùkún;Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.

21 “Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jákọ́bù,kò sì rí búburú kankan nínú Ísírẹ́lì. Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.

22 Ọlọ́run mú wọn jáde láti Éjíbítì wá,wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.

23 Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jákọ́bù,tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Ísírẹ́lì.Nísinsìnyìí a ó sọ nípa ti Jákọ́bùàti Ísírẹ́lì, ‘Wo ohun tí Olúwa ti ṣe!’

24 Àwọn ènìyàn dìde bí abo kìnnìún;wọ́n dìde bí i kìnnìúntí kì í sinmi títí yóò fi pa ìkógún jẹtàbí mu ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó fi ara pa.”

25 Nígbà náà ni Bálákì sọ fún Bálámù pé, “O ko fi wọ́n bú tàbí bùkún wọn rárá!”

26 Bálámù dáhùn pé, “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé mo gbọdọ̀ Ṣe ohun tí Olúwa bá sọ?”

Ọ̀rọ̀ Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀kẹ́ta Bálámù

27 Nígbà náà Bálákì sọ fún Bálámù pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”

28 Bálákì gbé Bálámù wá sí orí òkè Péórì, tí ó kọjú sí ihà.

29 Bálámù sọ pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.”

30 Bálákì sì ṣe bí Bálámù ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36