Nọ́ḿbà 3 BMY

Àwọn Ẹ̀yà Léfì

1 Ìwọ̀nyí ni ìdílé Árónì àti Mósè ní ìgbà tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ní òkè Sínáì.

2 Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀nyí, Nádábù ni àkọ́bí, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.

3 Orúkọ àwọn ọmọ Árónì nìwọ̀n yìí, àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn, àwọn tí a fi joyè àlùfáà láti siṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

4 Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù ti kú níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n rú iná àjèjì níwájú Olúwa nínú ijù Sínáì, àwọn méjèèjì kò sì ní ọmọ. Báyìí Élíásárì àti Ítamárì ló sisẹ́ àlùfáà nígbà ayé Árónì baba wọn.

5 Olúwa sọ fún Mósè pé,

6 “Kó ẹ̀yà Léfì wá, kí o sì fà wọ́n fún Árónì àlùfáà láti máa ràn-án lọ́wọ́.

7 Wọn yóò máa ṣiṣẹ́ fún un àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn ní Àgọ́ Ìpàdé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́.

8 Wọn yóò máa tọ́jú gbogbo ohun èlò inú Àgọ́ Ìpàdé, wọn yóò sì máa ṣe ojúṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àgọ́.

9 Fi ẹ̀yà Léfì jìn Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn nìkan ni a fi fún Árónì nínú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

10 Kí o sì yan Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣiṣẹ́ àlùfáà; ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ pípa ni kí ẹ pa á.”

11 Olúwa tún sọ fún Mósè pé,

12 “Báyìí èmi fúnra mi ti mú ẹ̀yà Léfì láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dípò gbogbo àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì. Ti èmi ni àwọn ọmọ Léfì,

13 nítorí pé ti èmi ni gbogbo àkọ́bí. Ní ọjọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti ya gbogbo àkọ́bí sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yálà ti ènìyàn tàbí ti ẹranko. Gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ti èmi. Èmi ni Olúwa.”

Kíka Àwọn Ọmọ Léfì

14 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè ní ihà Ṣínáì pé,

15 “Ka àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn kí o ka gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ oṣù kan sókè”

16 Mósè sì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

17 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì:Gáṣónì, Kóhátì àti Mérárì.

18 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Gáṣónì:Líbínì àti Ṣíméhì.

19 Àwọn ìdílé Kóhátì ni:Ámírámù, Ísíhárì, Hébírónì àti Yúsíélì.

20 Àwọn ìdílé Mérárì ni:Málì àti Músì.Wọ̀nyí ni ìdílé Léfì gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn:

21 Ti Gáṣónì ni ìdílé Líbínì àti Ṣíméhì; àwọn ni ìdílé Gásónì.

22 Iye àwọn ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, jẹ́ ẹgbàata ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (7,500).

23 Àwọn ìdílé Gáṣónì yóò pa ibùdó sí ìhà ìwọ̀ oòrùn lẹ́yìn àgọ́.

24 Olórí àwọn ìdílé Gáṣónì ni Eliásáfì ọmọ Láélì.

25 Iṣẹ́ àwọn ìdílé Gásónì nínú Àgọ́ Ìpàdé ni pé àwọn yóò máa tọ́jú àgọ́, ìbòrí àgọ́, aṣọ títa ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,

26 aṣọ títa ti àgbàlá, aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, àwọn okùn rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

27 Ti Kóhátì ní ìdílé Ámírámù, Ísíhárì, Hébírónì àti Yúsíélì, wọ̀nyí ni ìran Kóhátì

28 Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mẹ́rin ó lé ẹgbẹ̀ta, (8,600) tí yóò máa ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́.

29 Àwọn ìdílé Kóhátì yóò pa ibùdó wọn sí ìhà gúúṣù ní ẹ̀gbẹ́ àgọ́.

30 Olórí àwọn ìdílé Kóhátì ni Élísáfì ọmọ Yúsíélì.

31 Àwọn ni yóò máa tọ́jú àpótí ẹ̀rí, tabílì, ọ̀pá fìtílà, àwọn pẹpẹ, gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ tí à ń lò fún iṣẹ́ ìsìn, aṣọ títa àti gbogbo ohun tó jẹ mọ́ lílò wọn.

32 Élíásárì ọmọ Árónì àlùfáà ni alákóso gbogbo àwọn olórí ìdílé Léfì. Òun ni wọ́n yàn lórí gbogbo àwọn tí yóò máa tọ́jú ibi mímọ́.

33 Ti Mérárì ni ìran Málì àti Múṣì, àwọn ni ìran Mérárì.

34 Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).

35 Olórí àwọn ìdílé ìran Mérárì ni Súríélì ọmọ Ábíháílì, wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.

36 Àwọn ìran Mérárì ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn;

37 Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.

38 Mósè àti Árónì pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀ oòrùn níwájú Àgọ́ Ìpàdé. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.

39 Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Léfì tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè àti Árónì gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá (22,000).

40 Olúwa sọ fún Mósè pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Ísírẹ́lì láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

41 Kí o sì gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa.”

42 Mósè sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

43 Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).

44 Olúwa tún sọ fún Mósè pé,

45 Gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Tèmi ni àwọn ọmọ Léfì. Èmi ni Olúwa.

46 Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Ísírẹ́lì tó ju iye àwọn ọmọ Léfì lọ,

47 ìwọ yóò gba sẹ́kẹ́lì márùn ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gérà.

48 Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Ísírẹ́lì tó lé yìí, ni kí o kó fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀.

49 Nígbà náà ni Mósè gba owó ìràpádà àwọn ènìyàn tó sẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì ti ra àwọn yóòkù padà.

50 Mósè sì gba egbéje ṣékélì ó dín márùndínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

51 Mósè sì kó owó ìràpadà yìí fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti paá láṣẹ fún un.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36