1 Míríámù àti Árónì sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiópíà.
2 Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mósè nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.
3 (Mósè sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ènìyàn ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).
4 Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mósè, Árónì àti Míríámù pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta.
5 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ̀n ìkúùkù, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Árónì àti Míríámù. Àwọn méjèèjì sì bọ́ ṣíwájú,
6 Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi:“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrin yínÈmi Olúwa a máa fara à mi hàn án ní ojúran,Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.
7 Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mósè ìránṣẹ́ mi:ó jẹ́ olótítọ́ nínú gbogbo ilé mi.
8 Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,ó rí àwòrán OlúwaKí ló wá dé tí ẹ̀yin kò se bẹ̀rùláti sọ̀rọ̀ òdì sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”
9 Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.
10 Nígbà tí ìkúùkù kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Míríámù di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Árónì sì padà wo Míríámù ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀,
11 Ó sì sọ fún Mósè pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn.
12 Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”
13 Torí èyí Mósè sì kígbe sí Olúwa, “Olúwa, dákun mú un lára dá!”
14 Olúwa sì dá Mósè lóhùn, “Bí bàbá rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.”
15 Míríámù sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀ ṣíwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Míríámù fi wọ inú ibùdó padà.
16 Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Hásérótì, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Páránì.