1 Nígbà tí Móṣè ti pári gbígbé àgọ́ dúró, ó ta òróró sí i, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀, Ó tún ta òróró sí pẹpẹ, ó sì yà á sí mímọ́ pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀.
2 Nígbà náà ni àwọn olórí Ísírẹ́lì, àwọn ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àwọn alábojútó àwọn tí a kà náà mú ọrẹ wá.
3 Wọ́n mú ọrẹ wọn wá ṣíwájú Olúwa: kẹ̀kẹ́ ẹrù mẹ́fà ti abo, àti akọ màlúù kan láti ọ̀dọ̀ olórí kọ̀ọ̀kan àti kẹ̀kẹ́ ẹrù kan láti ọ̀dọ̀ olórí méjì. Wọ́n sì kó wọn wá sí iwájú àgọ́.
4 Olúwa sọ fún Mósè pé:
5 “Gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ wọn, kí wọ́n ba à lè wúlò fún iṣẹ́ inú Àgọ́ Ìpàdé. Kó wọn fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe nílò rẹ̀.”
6 Mósè sì kó àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù àti akọ màlúù náà fún àwọn ọmọ Léfì.
7 Ó fún àwọn ọmọ Gáṣónì ní kẹ̀kẹ́ méjì àti akọ màlúù mẹ́rin, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́.
8 O fún àwọn ọmọ Mérárì ní kẹ̀kẹ́ mẹ́rin àti akọ màlúù mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn ṣe jẹ mọ́. Gbogbo wọn wà lábẹ́ àkóso Ítamárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà.
9 Ṣùgbọ́n Mósè kò fún àwọn ọmọ Kóhátì ní nǹkan kan nítorí pé èjìká wọn ni wọn yóò fi ru àwọn ohun mímọ́ èyí tí ó jẹ́ ojúṣe tiwọn.
10 Nígbà tí a ta òróró sórí pẹpẹ. Àwọn olórí mú àwọn ọrẹ wọn wá fún ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá ṣíwájú pẹpẹ.
11 Nítorí tí Olúwa ti sọ fún Mósè pé, “Olórí kọ̀ọ̀kan ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ni yóò máa mú ọrẹ tirẹ̀ wá ṣíwájú pẹpẹ.”
12 Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù láti inú ẹ̀yà Júdà.
13 Ọrẹ rẹ̀ jẹ́ àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
14 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
15 Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun,
16 Akọ ewurẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
17 Màlúù méjì, àgbò márùn ún, akọ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Násónì ọmọ Ámínádábù.
18 Ní ọjọ́ kéjì ni Nétaníẹ́lì ọmọ Súárì olórí àwọn ọmọ Ísákárì mú ọrẹ tirẹ̀ wá.
19 Ọrẹ tí ó kó wá ní àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) sékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí á fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
20 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ sékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,
21 Ọ̀dọ́ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun;
22 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
23 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-un àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-un tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Nètaníẹ́lì ọmọ Súárì.
24 Élíábù ọmọ Hélónì, olórí àwọn ọmọ Sébúlónì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹ́ta.
25 Àwọn ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọn rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) àti ṣékélì fàdákà, àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì,
26 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
27 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
28 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
29 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ márùn ún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn o fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Élíábù ọmọ Hélónì.
30 Élíṣúrì ọmọ Ṣédéúrì olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ kẹrin.
31 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
32 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí,
33 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
34 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
35 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Élísúrì ọmọ Ṣédéúrì.
36 Ṣélúmíélì ọmọ Suriṣádáì, olórí àwọn ọmọ Símónì ni ó mú ọrẹ wá ní ọjọ́ karùn-ún.
37 Ọrẹ tí ó kó wá ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ́;
38 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
39 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
40 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
41 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Sélúmíélì ọmọ Surisádáì.
42 Eliásáfì ọmọ Déúélì olórí àwọn ọmọ Gáádì ní ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹfà.
43 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí iwọn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò bí ẹbọ ohun jíjẹ
44 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí
45 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun
46 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀
47 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Eliásáfì ọmọ Déúélì.
48 Élísámà ọmọ Ámíhúdì, olórí àwọn ọmọ Éfúráímù ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ keje.
49 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ
50 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí
51 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun
52 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
53 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Élísámà ọmọ Ámíhúdì.
54 Gàmálíèlì ọmọ Pédáṣúrì, olórí àwọn ọmọ Mánásè ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹjọ.
55 Ọrẹ tirẹ̀ ni, àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
56 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
57 akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
58 akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
59 màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Gámálíélì ọmọ Pédásúrì.
60 Ábídánì ọmọ Gídíónì, olórí àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹsan-an.
61 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
62 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
63 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
64 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
65 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Ábídánì ọmọ Gídíónì.
66 Áhíésérì ọmọ Ámíṣádáyì, olórí àwọn ọmọ Dánì ni ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kẹwàá.
67 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo sílifà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
68 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
69 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
70 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
71 Màlúù méjì, àgbò márùn-ùn, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fí rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ ọmọ Dánì.
72 Págíélì ọmọ Ókíránì, olórí àwọn ọmọ Áṣérì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kọkànlá.
73 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì àti àwokòtò tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
74 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì mẹ́wàá tí ó kún fún tùràrí;
75 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun.;
76 Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
77 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, tí wọn ó fí rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Págíélì ọmọ Ókíránì.
78 Áhírà ọmọ Énánì, olórí àwọn Náfítanì ni ó mú ọrẹ rẹ̀ wá ní ọjọ́ kejìlá.
79 Ọrẹ rẹ̀ ni àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje (130) ṣékélì, àti àwokótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin (70) ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, àwo kọ̀ọ̀kan sì kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
80 Àwo wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì méwàá tí ó kún fún tùràrí;
81 Akọ ọ̀dọ́ màlúù kan àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan fún ẹbọ sísun;
82 Akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀;
83 Màlúù méjì, àgbò márùn-ún, akọ ewúrẹ́ márùn-ún àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan márùn-ún, wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Èyí ni ọrẹ Áhírà ọmọ Énánì.
84 Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá.
85 Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje (130) ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin (70). Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá ṣékélì (2,400) gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.
86 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwó wúrà méjìlá tí tùràrí kún inú wọn ṣékélì mẹ́wàá mẹ́wàá gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Àpapọ̀ ìwọ̀n gbogbo àwo wúrà jẹ́ ọgọ́fà ṣékélì (120)
87 Àpapọ̀ iye ẹran fún ẹbọ sísun jẹ́ akọ ọ̀dọ́ màlúù méjìlá, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan méjìlá pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ. Akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ méjìlá.
88 Àpapọ̀ iye ẹran fún ọrẹ àlàáfíà jẹ́ màlúù mẹ́rìnlélógún (24), ọgọ́ta (60) àgbò, ọgọ́ta (60) akọ ewúrẹ́ àti ọgọ́ta (60) akọ ọ̀dọ́ màlúù ọlọ́dún kan. Wọ̀nyí ni ọrẹ ìyàsímímọ́ pẹpẹ lẹ́yìn tí a ta òróró sí i.
89 Nígbà tí Mósè wọ inú Àgọ́ Ìpàdé láti bá Olúwa sọ̀rọ̀, Olúwa sì sọ̀rọ̀ sí i láti àárin àwọn kérúbù méjì láti orí ìtẹ́ àánú tó bo àpótí ẹ̀rí, ohùn náà sì bá Mósè sọ̀rọ̀.