Nọ́ḿbà 33 BMY

Ìpele Ìrìnàjò Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì

1 Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Íjibítì jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mósè àti Árónì.

2 Mósè sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa; Wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.

3 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò láti Rámésesì ní ọjọ́ kẹ́ẹdógún osù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọja. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Éjíbítì.

4 Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrin wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.

5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Rámésesì wọ́n sì pàgọ́ sí Ṣúkótù.

6 Wọ́n kúrò ní Súkótù, wọ́n sì pàgọ́ sí Étamù, ní ẹ̀bá ihà.

7 Wọ́n kúrò ní Étamù, wọ́n padà sí Háhírótù sí ìlà oòrùn Báálì ti Ṣéfónì, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Mégídólù.

8 Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní ìwájú Háhírótù, wọ́n sì la àárin òkun kọjá lọ sí ihà: Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní ihà Étamù, wọ́n sì pàgọ́ sí Márà.

9 Wọ́n kúrò ní Márà wọ́n sì lọ sí Élímù, níbi tí orísun omi méjìlá (12) àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin (70) gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.

10 Wọ́n kúrò ní Élímù wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.

11 Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú ihà Ṣínì.

12 Wọ́n kúrò nínú ihà Ṣínì wọ́n sì pàgọ́ sí ihà Dófákà.

13 Wọ́n kúrò ní Dófákà wọ́n sì pàgọ́ ní Álúṣì.

14 Wọ́n kúrò ní Álúṣì wọ́n sì pàgọ́ ní Réfídímù níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.

15 Wọ́n kúrò ní Refídímù wọ́n sì pàgọ́ ní ihà Ṣínáì.

16 Wọ́n kúrò ní ihà Ṣínáì wọ́n sì pàgọ́ ní Kabirotu-Hátafà.

17 Wọ́n kúrò ní Kabirotu-Hátafà wọ́n sì pàgọ́ ní Hásérótì.

18 Wọ́n kúrò ní Hásérótì wọ́n sì pàgọ́ ní Rítímà.

19 Wọ́n kúrò ní Rítímà wọ́n sì pàgọ́ ní Rímónì-Pérésì.

20 Wọ́n kúrò ní Rímóni Pérésì wọ́n sì pàgọ́ ní Líbínà.

21 Wọ́n kúrò ní Líbínà wọ́n sì pàgọ́ ní Rísà.

22 Wọ́n kúrò ní Rísà wọ́n sì pàgọ́ ní Kehelátà.

23 Wọ́n kúrò ní Kehelátà wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Ṣéférì.

24 Wọ́n kúrò lórí òkè Ṣéférì wọ́n sì págọ́ ní Hárádà.

25 Wọ́n kúrò ní Hárádà wọ́n sì pàgọ́ ní Mákélótì.

26 Wọ́n kúrò ní Mákélótì wọ́n sì pàgọ́ ní Táhátì.

27 Wọ́n kúrò ní Táhátì wọ́n sì pàgọ́ ní Térà.

28 Wọ́n kúrò ní Térà wọ́n sì pàgọ́ ní Mítíkà.

29 Wọ́n kúrò ní Mítíkà wọ́n pàgọ́ ní Hásímónà.

30 Wọ́n kúrò ní Hásímónà wọ́n sì pàgọ́ ní Mósérótù.

31 Wọ́n kúrò ní Mósérótù wọ́n sì pàgọ́ ní Bene-Jákánì.

32 Wọ́n kúrò ní Bene-Jákánì wọ́n sì pàgọ́ ní Hori-Hágidigádì.

33 Wọ́n kúrò ní Hori-Hágidigádì wọ́n sí pàgọ́ ní Jótíbátà.

34 Wọ́n kúrò ní Jótíbátà wọ́n sì pàgọ́ ní Ábírónà.

35 Wọ́n kúrò ní Ábírónà wọ́n sì pàgọ́ ní Esoni-Gébérì.

36 Wọ́n kúrò ní Esoni-Gébérì wọ́n sì pàgọ́ ní Kádésì nínú ihà Ṣínì.

37 Wọ́n kúrò ní Kádésì wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hórì, lẹ́bá Édómù.

38 Nípa àsẹ Olúwa, Árónì àlùfáà gùn orí òkè Hórì, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kárun, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá.

39 Árónì jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hórì.

40 Àwọn ará Kénánì, ọba Árádì, tí ń gbé ìhà gúṣù ní ilẹ̀ Kénánì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ̀.

41 Wọ́n kúrò ní orí òkè Hórì, wọ́n sì pàgọ́ ní Ṣálímónà.

42 Wọ́n kúrò ní Ṣálímónà wọ́n sì pàgọ́ ní Púnónì.

43 Wọ́n kúrò ní Púnónì wọ́n sì pàgọ́ ní Óbótù.

44 Wọ́n kúrò ní Óbótù wọ́n sì pàgọ́ ní Iye-Ábárímù, ní agbégbé Móábù.

45 Wọ́n kúrò ní Íyímù wọ́n sì pàgọ́ ní Díbónì-Gádì.

46 Wọ́n kúrò ní Dibónì-Gádì wọ́n sì pàgọ́ ní Alimoni-Díbílátamù.

47 Wọ́n kúrò ní Alimoni-Díbílátaímù wọ́n sì pàgọ́ sí orí òkè Ábárímù lẹ́bá Nébò.

48 Wọ́n kúrò ní orí òkè Ábárímù wọ́n sì pàgọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá Jọ́dánì ní ìkọjá Jẹ́ríkò.

49 Níbí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù wọ́n pàgọ́ lẹ́gbẹ́ Jọ́dánì láti Bẹti-Jéíóù títí dé Abeli-Sítímù

50 Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù, lẹ́bá Jọ́dánì, létí Jẹ́ríkò, Olúwa sọ fún Mósè pé,

51 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ní ìgbà tí ẹ̀yin bá ń rékọjá odò Jọ́dánì lọ sí Kénánì,

52 Lé gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín. Run gbogbo àwòrán ère wọn àti gbogbo ère dídá wọn, kí ẹ sì wó gbogbo ibi gíga wọn palẹ̀.

53 Ẹ gba ilẹ̀ náà, kí ẹ̀yin sì máa gbé inú ún rẹ̀, nítorí èmi ti fi ilẹ̀ náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní yín.

54 Ẹ̀yin pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú kèké, gẹ́gẹ́ bí ìdílé yín. Fún ọ̀pọ̀ ni kí ẹ̀yin ó fi ilẹ̀ ìní púpọ̀ fún, àti fún díẹ̀, ni kí ẹ̀yin kí ó fi ilẹ̀ ìní díẹ̀ fún. Ohunkóhun tí ó bá bọ́ sí ọ̀dọ̀ wọn nípa kèké yóò jẹ́ ti wọn. Pín wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìran wọn.

55 “ ‘Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lé àwọn ará ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, àwọn tí ẹ bá jẹ́ kí ó kù yóò di ọfà nínú ojú yín, àti ẹ̀gún ní ìhà yín. Wọn yóò fún yín ní wàhálà ní ilẹ̀ náà tí ẹ̀yin yóò gbé.

56 Nígbà náà, èmi yóò ṣe sí yín, ohun tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.’ ”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36