Nọ́ḿbà 20 BMY

Omi Láti Inú Àpáta.

1 Ní osù kìn-ní-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Ísírẹ́lì gúnlẹ̀ sí pápá Sínì, wọ́n sì dúró ní Kádésì. Níbẹ̀ ni Míríámù kú, wọ́n sì sin ín.

2 Nísinyìí kò sì sí omi fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kóra wọn jọ lòdì sí Mósè àti Árónì,

3 Wọ́n bá Mósè jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arakùnrin ti kú níwájú Olúwa!

4 Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí ihà yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa báà kú síbí?

5 Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Éjíbítì wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èṣo àjàrà tàbí pamonganati. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhín-ín!”

6 Mósè àti Árónì kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n.

7 Olúwa sọ fún Mósè pé,

8 “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Árónì arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ójú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu”

9 Báyìí ni Mósè mú ọ̀pá láti iwájú Olúwa wá, gẹ́gẹ́ bí ó ti paláṣẹ fún un.

10 Òun àti Árónì pe àwọn ènìyàn jọ sí ojú kan níwájú àpáta, Mósè sì sọ fún wọn, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yín ọlọ̀tẹ̀, àwa kì yóò lè mú omi jáde láti inú àpáta yìí wá bí?”

11 Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

12 Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé, “Nítorí pé ẹ̀yin kò gbà mí gbọ́ tó láti bu ọlá fún mi níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìwọ kò ní kó àwọn ìjọ ènìyàn yìí dé ilẹ̀ tí mo fún wọn.”

13 Èyí ni omi ti Méríbà, níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Olúwa jà àti ibi tí O ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni mímọ́ láàrin wọn.

Édómù Ṣẹ́ Ísírẹ́lì

14 Mósè sì ránṣẹ́ láti Kádésì sí ọba Édómù, wí pé:“Èyí ni nǹkan tí arákùnrin rẹ Ísírẹ́lì sọ: Ìwọ ti mọ̀ nípa gbogbo ìnira, tí ó wá sí orí wa.

15 Àwọn bàbá ńlá wa sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì, a sì gbé ibẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ará Éjíbítì ni wá lára àti àwọn bàbá wa,

16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì.“Báyìí àwa wà ní Kádésì, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

17 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”

18 Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé:“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”

19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé:“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

20 Wọ́n tún dáhùn wí pé:“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun.

21 Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Ikú Árónì

22 Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì.

23 Ní orí òkè Hórì, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Édómù Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

24 “Árónì yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Méríbà.

25 Mú Árónì àti ọmọ rẹ̀ Élíásárì lọ sí orí òkè Hórì.

26 Bọ́ aṣọ Árónì kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, nítorí pé Árónì yóò kú ṣíbẹ̀.”

27 Mósè sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa láṣẹ: Wọ́n lọ sí orí òkè Hórì ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn.

28 Mósè bọ́ aṣọ Árónì ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Élíásárì, Árónì sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mósè àti Élíásárì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè,

29 Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Árónì ti kú, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36