4 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ́ wọn fi ìtara bèèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!
5 Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Éjíbítì, apálá, ègúsí, ewébẹ̀ àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn
6 Ṣùgbọ́n báyìí gbogbo ara wa ti gbẹ, kò sí ohun mìíràn láti jẹ àfi mánà nìkan tí a rí yìí!”
7 Mánà náà dàbí èso koriáńdérì, ìrísí rẹ̀ sì dàbí oje igi.
8 Àwọn ènìyàn náà ń lọ káàkiri láti kó o, wọn ó lọ̀ ọ́ lórí ọlọ tàbí kí wọ́n gún un nínú odó. Wọ́n le ṣè é nínú ìkòkò tàbí kí wọn ó fi ṣe àkàrà, adùn rẹ̀ yóò sì dàbí adùn ohun tí a fi òróró ṣe.
9 Nígbà tí ìrì bá ṣẹ̀ sí ibùdó lórí ni mánà náà máa ń bọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
10 Mósè sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sunkún ní gbogbo ìdílé wọn, oníkálukú ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ tirẹ̀. Olúwa sì bínú gidigidi. Inú Mósè sì bàjẹ́ pẹ̀lú.