15 Láti inú ẹ̀yà Gádì, Géúlì ọmọ Mákì.
16 Wọ̀nyí ni orukọ àwọn ènìyàn tí Mósè rán láti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò. (Ósísà ọmọ Núnì ni Mósè sọ ní Jóṣúà.)
17 Nígbà tí Mósè rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà Gúúsù lọ títi dé àwọn ìlú olókè
18 Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré.
19 Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi?
20 Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èṣo àjàrà gíréépù.)
21 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Ṣínì títí dé Réhóbù lọ́nà Lébò Hámátì.