1 Olúwa sọ fún Mósè pé;
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi ó fún yin gẹ́gẹ́ bí ibùgbé
3 tí ẹ sì mú ọrẹ àfinásun wá, yálà nínú ọ̀wọ́ ẹran gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, bóyá ọrẹ sísun tàbí ẹbọ sísun, láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí ọrẹ àtinúwá,
4 nígbà náà ni kí ẹni tí ó bá mú ọrẹ rẹ̀ wá, yóò tún mú ẹbọ ohun jíjẹ ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúná pẹ̀lú ìdásímẹ́rin òṣùwọ̀n òróró wá ṣíwájú Olúwa.
5 Pẹ̀lú ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan yálà fún ọrẹ tabí ẹbọ sísun ni, kí ẹ pèsè ìdá sí mẹ́rin òṣùwọ̀n wáìnì gẹ́gẹ́ bí ohun mímu.
6 “ ‘Fún àgbò kan ni kí ẹ pèsè ọrẹ ohun jíjẹ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n òróró pò.
7 Àti ìdá kan nínú mẹ́ta òṣùwọ̀n wáìnì fún ọrẹ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.