10 Ó ti mú àwọn ènìyàn yín tó jẹ́ ọmọ Léfì súnmọ́ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí ẹ tún ń wá ọnà láti ṣiṣẹ́ àlùfáà.
11 Olúwa ni ìwọ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Árónì jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”
12 Mósè sì ránṣẹ́ sí Dátanì àti Ábírámù àwọn ọmọ Élíábù. Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé “Àwa kò ní í wá!
13 Kò ha tó gẹ́ ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú ihà yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di Olúwa lé wa lórí bí?
14 Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tó ń ṣàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní wa fún wa. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kò ní wá!”
15 Nígbà náà ni Mósè bínú gidigidi, ó sì sọ fún Olúwa pé, “Má ṣe gba ọrẹ wọn, èmi kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì pa ẹnikẹ́ni nínú wọn lára!”
16 Mósè sọ fún Kórà pé, “Ìwọ àti ọmọ lẹ́yìn rẹ gbọdọ̀ fara hàn níwájú Olúwa lọ́la—gbogbo yín, ìwọ, àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Árónì.