19 Nígbà tí Kórà kó gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé, ògo Olúwa sì farahan gbogbo ìjọ ènìyàn.
20 Olúwa sì sọ fún Mósè àti Árónì pé,
21 “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí ń ba à le pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.”
22 Ṣùgbọ́n Mósè àti Árónì dojúbolẹ̀ wọ́n sì kígbe sókè pé, “Ọlọ́run, Ọlọ́run ẹ̀mi gbogbo ènìyàn, Ìwọ ó wa bínú sí gbogbo ìjọ ènìyàn nígbà tó jẹ́ pé ẹnì kan ló ṣẹ̀?”
23 Olúwa tún sọ fún Mósè pé,
24 “Sọ fún ìjọ ènìyàn pé, ‘Kí wọ́n jìnnà sí àgọ́ Kórà, Dátanì àti Ábírámù.’ ”
25 Mósè sì dìde lọ bá Dátanì àti Ábírámù àwọn olórí Ísírẹ́lì sì tẹ̀lé.