5 Ó sì sọ fún Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la ni Olúwa yóò fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ àti ẹni tó mọ́ hàn, yóò sì mú kí ẹni náà súnmọ́ òun. Ẹni tí ó bá yàn ni yóò mú kí ó súnmọ́ òun.
6 Kí Kórà àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe èyí, Ẹ mú àwo tùràrí.
7 Kí ẹ sì fi iná àti tùràrí sínú rẹ̀ lọ́la níwájú Olúwa, yóò si se, ọkùnrin tí Olúwa bá yàn oun ni. Ẹ̀yin ọmọ Léfì, ẹ ti kọjá ààyè yín!”
8 Mósè sì tún sọ fún Kórà pé, “Ẹ gbọ́ báyìí o, ẹ̀yin ọmọ Léfì!
9 Kò ha tọ́ fún yín pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti yà yín sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, tó sì mú yín súnmọ́ ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ Olúwa àti láti dúró ṣiṣẹ́ ìsìn níwájú àwọn ènìyàn?
10 Ó ti mú àwọn ènìyàn yín tó jẹ́ ọmọ Léfì súnmọ́ ara rẹ̀, ṣùgbọ́n báyìí ẹ tún ń wá ọnà láti ṣiṣẹ́ àlùfáà.
11 Olúwa ni ìwọ àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ takò. Ta a ni Árónì jẹ́ tí ẹ̀yin ó fi kùn sí i?”