1 Olúwa sì sọ fún Mósè pé
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí o sì gba ọ̀pá méjìlá lọ́wọ́ wọn, ọ̀kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ olórí ìdílé ẹ̀yà ìran wọn, kọ orúkọ ènìyàn kọ̀ọ̀kan sí ara ọ̀pá rẹ̀.
3 Lórí ọ̀pá Léfì kọ orúkọ Árónì, nítórí ọ̀pá kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ wà fún olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan tí yóò jẹ́ orí fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan.
4 Kó wọn sí Àgọ́ Ìpàdé níwájú Ẹ̀rí níbi tí èmi ti ń pàdé yín.