11 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500).
12 Ẹ̀yà Símónì ni yóò pa ibùdó tẹ́lé wọn. Olórí Símónì ni Ṣélúmíélì ọmọ Surisadáì.
13 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300).
14 Ẹ̀yà Gáádì ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gáádì ni Eliásáfì ọmọ Déúélì.
15 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́ta (45,650).
16 Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Rúbẹ́nì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rún ó lé àádọ́tàlélégbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.
17 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì Àti Àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀ṣíwájú láàrin ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀ṣíwájú ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láàyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.