2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àṣíá ìdílé wọn.”
3 Ní ìlà oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn ni kí ìpín ti Júdà pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Júdà ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù.
4 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).
5 Ẹ̀yà Ísákárì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ísákárì ni Nìtaníẹ́lì ọmọ Súárì.
6 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó (54,400).
7 Ẹ̀yà Sébúlúnì ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sébúlónì ni Élíábù ọmọ Hélónì.
8 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (57,400).