5 Ẹ̀yà Ísákárì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ísákárì ni Nìtaníẹ́lì ọmọ Súárì.
6 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó (54,400).
7 Ẹ̀yà Sébúlúnì ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sébúlónì ni Élíábù ọmọ Hélónì.
8 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (57,400).
9 Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Júdà, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́taléláàdọ́rin ó lé irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.
10 Ní ìhà gúsù ni ìpín ti Rúbẹ́nì pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Rúbẹ́nì ni Elisúrì ọmọ Ṣedúérì.
11 Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500).