1 Ní osù kìn-ní-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Ísírẹ́lì gúnlẹ̀ sí pápá Sínì, wọ́n sì dúró ní Kádésì. Níbẹ̀ ni Míríámù kú, wọ́n sì sin ín.
2 Nísinyìí kò sì sí omi fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kóra wọn jọ lòdì sí Mósè àti Árónì,
3 Wọ́n bá Mósè jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arakùnrin ti kú níwájú Olúwa!
4 Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí ihà yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa báà kú síbí?