16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sunkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán ańgẹ́lì kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Éjíbítì.“Báyìí àwa wà ní Kádésì, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.
17 Jọ̀wọ́ jẹ́ kí a gba orílẹ̀ èdè rẹ kọjá, Àwa kì yóò gba inú oko tàbí ọgbà àjàrà rẹ kọjá, tàbí mu omi láti inú kàǹga. A ó ma kọjá ní òpópónà ọba, àwa kì yóò yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì títí àwa yóò fi kọjá ní ilẹ̀ rẹ.”
18 Ṣùgbọ́n Édómù dáhùn pé:“Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun síyín a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”
19 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáhùn pé:“A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkankan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”
20 Wọ́n tún dáhùn wí pé:“Ẹ kò lè kọjá.”Nígbà náà ni Édómù jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ ogun.
21 Nígbà tí Édómù sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Ísírẹ́lì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
22 Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì jáde láti Kádésì wọ́n sì wá sí orí òkè Hórì.