2 Nísinyìí kò sì sí omi fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kóra wọn jọ lòdì sí Mósè àti Árónì,
3 Wọ́n bá Mósè jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arakùnrin ti kú níwájú Olúwa!
4 Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí ihà yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa báà kú síbí?
5 Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Éjíbítì wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èṣo àjàrà tàbí pamonganati. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhín-ín!”
6 Mósè àti Árónì kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n.
7 Olúwa sọ fún Mósè pé,
8 “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Árónì arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ójú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu”