25 Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ìlú Ámórì wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Hésíbónì, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká.
26 Hésíbónì ni ìlú Ṣíhónì ọba àwọn ará Ámórì, ẹni tí ó bá ọba ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Ánónì.
27 Ìdí nì yí tí akọrin sọ wí pé:“Wá sí Hésíbónì kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;jẹ́ kí ìlú Ṣíhónì padà bọ̀ sípò.
28 “Iná jáde láti Hésíbónì,ọ̀wọ́ iná láti Ṣíhónì.Ó jó Árì àti Móábù run,àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Ánónì.
29 Ègbé ní fún ọ, ìwọ Móábù!Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kémósì!Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀san àti ọmọ rẹ̀ obìnringẹ́gẹ bí ìgbékùn fún Ṣíhónì ọba àwọn Ámórì.
30 “Ṣùgbọ́n ati bì wọ́n ṣubú;A ti pa wọ́n run títí dé Díbónì.A sì ti run wọ́n títí dé Nófà, tí ó sì fí dé Médébà.”
31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń gbé ní ilẹ̀ Ámórì.