5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Olúwa àti Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì kí a ba le wá kú sí ihà yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kóríra oúnjẹ tí kò dára yìí!”
6 Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárin wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kú.
7 Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mósè wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí a sọ̀rọ̀ òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mósè gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.
8 Olúwa sọ fún Mósè pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”
9 Nígbà náà ni Mósè sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.
10 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì péjọ sí Óbótì.
11 Wọ́n gbéra ní Óbótì wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-àbárímù, ní ihà tí ó kọjú sí Móábù ní ìdojúkọ ìlà oòrùn.