17 ti Árédì, ìdílé Árédì;ti Árólì, ìdílé Árólì.
18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gádì tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
19 Àwọn ọmọ Júdà ni Érì àti Ónánì, ṣùgbọ́n Érì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénánì.
20 Àti àwọn ọmọ Júdà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Ṣélà, ìdílé Ṣélà;ti Pérésì, ìdílé Pérésì;ti Sérà, ìdílé Ṣérà.
21 Àwọn ọmọ Pérésì:ti Hésírónì, ìdílé Hésírónì;ti Hámúlù, ìdílé Hámúlù.
22 Wọ̀nyí ni ìdílé Júdà; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).
23 Àwọn ọmọ Isákárì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Tólà, ìdílé Tólà;ti Púfà, ìdílé Púfà;