24 ti Jáṣúbù, ìdílé Jáṣúbù;ti Ṣímírónì, ìdílé Ṣímírónì.
25 Wọ̀nyí ni ìdílé Isákárì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàáméjìlélọ́gbọ̀n ó léọ̀ọ́dúnrún (64,300).
26 Àwọn ọmọ Ṣebúlúnì gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:ti Sẹ́rẹ́dì, ìdílé Ṣẹ́rẹ́dì;ti Élónì, ìdílé Élónì;ti Jálélì, ìdílé Jálélì.
27 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebúlúnì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).
28 Àwọn ọmọ Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Mánásè àti Éfúráímù:
29 Àwọn ọmọ Mánásè:ti Mákírì, ìdílé Mákírì (Mákírì sì bí Gílíádì);ti Gílíádì, ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì.
30 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gílíádì:ti Íésérì, ìdílé Íésérì;ti Hélékì, ìdílé Hélékì