11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún Mósè.’ ”
12 Nígbá náà Olúwa sọ fún Mósè pé, “Lọ sì orí òkè Ábárímù yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
13 Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Árónì arákùnrin rẹ ṣe ṣe,
14 nítórí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Ṣínì, tí gbogbo yín se àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Méríbà ní Kádésì ní ihà Sínì.)
15 Mósè sọ fún Olúwa wí pé,
16 “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí
17 Láti má a darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùsọ́”