14 nítórí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Ṣínì, tí gbogbo yín se àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Méríbà ní Kádésì ní ihà Sínì.)
15 Mósè sọ fún Olúwa wí pé,
16 “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí
17 Láti má a darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùsọ́”
18 Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mósè pé, “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.
19 Jẹ́ kí ó dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì kí o sì fi àsẹ fún un ní ojú wọn.
20 Fún un ní ara àwọn àṣẹ rẹ kí gbogbo ìlú Ísírẹ́lì kí ó lè gbọ́ràn sí i lẹ́nu.