4 Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítórí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn arakùnrin baba wa.”
5 Nígbà náà Mósè mú ọ̀rọ̀ wọn wá ṣíwájú Olúwa.
6 Olúwa sì wí fún un pé,
7 “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣélófénátì ń sọ tọ̀nà. Ó gbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.
8 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀.
9 Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀.
10 Tí kò bá ní arakùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀.