15 Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ̀ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.
16 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé.
17 Ní ọjọ́ kẹẹ́dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.
18 Ní ọjọ́ kìn-ní-ní ni kí ẹ ṣe ìpàdé àjọ mímọ́ kí ẹ wá kí ẹ sì má ṣe iṣẹ́ kankan.
19 Ẹ rú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù.
20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;
21 pẹ̀lú ọ̀dọ̀ àgùntàn kọ̀ọ̀kan ida kan nínú mẹ́wà.