2 “Fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin yìí kí o sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ rí i wí pé ẹ gbé e wá sí iwájú mi ní àkókò tí a ti yàn, oúnjẹ ọrẹ ẹbọ mi tí a fi iná ṣe sí mi, gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí mi.’
3 Sọ fún wọn, ‘Èyí ní ọrẹ ẹbọ tí a fi iná sun tí ẹ gbọdọ̀ mú wá fún Olúwa: akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan aláìlábàwọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ọrẹ sísun ní ojojúmọ́.
4 Pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn kan ní òwúrọ̀ àti òmíràn ní àfẹ̀mọ́júmọ́.
5 Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ tí ó jẹ́ ìdámẹ́wàá éfà ìyẹ̀fun dáradára tí a pò pọ̀ mọ́ ìdámẹ́rin hínì òróró tí a yọ lára Ólífì.
6 Èyí ni ẹbọ sísun gbogbo ìgbà tí a fi lẹ́lẹ̀ ní òkè Sínáì gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn ẹbọ tí a fi iná sun fún Olúwa pẹ̀lú iná.
7 Àfikún ọrẹ ohun mímu rẹ gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́rin ti hínì dídé omi mímu tí ó kan pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́ àgùntàn. Da ẹbọ mímu náà síta sí Olúwa ní ibi mímọ́.
8 Pèsè ọ̀dọ́ àgùntàn kejì ní àfẹ̀mọ̀júmọ́, pẹ̀lú oríṣìí ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu èyí tí ó pèsè ní òwúrọ̀, èyí ni ẹbọ tí a fi iná ṣe, olóòrùn dídùn sí Olúwa.