20 Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;
21 pẹ̀lú ọ̀dọ̀ àgùntàn kọ̀ọ̀kan ida kan nínú mẹ́wà.
22 Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín.
23 Ṣe eléyí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀.
24 Báyìí ní kí ẹ ṣe se oúnjẹ fún ẹbọ tí a fi iná ṣe ní ojojúmọ́ fún ọjọ́ méje gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn sí Olúwa; ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi iná ṣe ní àfikún ẹbọ ohun jíjẹ àti ohun mímu.
25 Ní ọjọ́ kéje kí ẹ̀yin kí ó ní ìpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe isẹ́ kankan.
26 “ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò Àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ se iṣẹ́ kankan.