8 Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadesi-Báníyà láti lọ wo ilẹ̀ náà.
9 Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí Àfonífojì Ésíkólù tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn.
10 Ìbínú Olúwa sì dìde sí wọn ní ọjọ́ náà, ó sì búra, wí pé:
11 ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Éjíbítì ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Ábúráhámù, fún Ísáákì àti fún Jákọ́bù:
12 kò sí ẹnìkankan àyàfi Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì àti Jóṣúà ọmọ Núnì, nítorí wọ́n tẹ̀lé Olúwa tọkàntọkàn.’
13 Ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì mú wọn rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún, títí tí àwọn ìran tí wọ́n ṣe búburú ní ojú rẹ̀ fi lọ.
14 “Níbí ni ẹ̀yin wà, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ̀yin dìde ní ipò bàbá yín, ẹ sì jẹ́ kí ìbínú gbígbóná Olúwa ru sí Ísírẹ́lì.