1 Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní Jọ́dánì tí ó rékọjá láti Jẹ́ríkò, Olúwa sọ fún Mósè pé,
2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fún àwọn Léfì ní ilẹ̀ láti gbé lára ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jogún. Kí ẹ sì fún wọn ní ilẹ̀ lára pápá oko tútù, káàkiri ìlú.
3 Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.
4 “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Léfì, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbàá ìgbọ̀nwọ́ (1500) ẹsẹ̀ bàtà láti ògiri ìlú náà.