19 Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà; tí ó bá bá a, yóò pa á.
20 Tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń yan odì pẹ̀lú ìríra tí ẹlòmíràn tàbí ju nǹkan sí i pẹ̀lú èrò, tí ó sì kú.
21 Tàbí pẹ̀lú ìjà gbangba lù ú pẹ̀lú ìkúùkù tí ó sì kú, pípa ni a ó pa ẹni bẹ́ẹ̀; apànìyàn ni. Olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ yóò pa apànìyàn náà tí ó bá bá a.
22 “ ‘Ṣùgbọ́n bí ó bá fi nǹkan gún un lójijì láìṣọ̀ta, tàbí tí ó sọ ohunkóhun lù ú láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ ṣe
23 tàbí, láìri, ju òkúta sí tí ó lè pa á, tí ó sì kú, nígbà tí kì í ṣe ọ̀ta rẹ̀, láti ṣe é léṣe,
24 Àwọn àpèjọ gbúdọ̀ dájọ́ láàrin rẹ̀ àti olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà.
25 Àpèjọ gbọ́dọ̀ dá ààbò bo ẹni tí a fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn, kí a sì ran-an padà lọ sí ìlú ìsásí tí ó ti wá. Ó gbúdọ̀ dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí olórí àlùfáà bá kú, ẹni tí a fi àmì òróró yàn.