1 Àwọn olórí ìdílé Gílíádì, ọmọkùnrin Mákírì ọmọ Mánásè tí ó wá láti ara ìdílé ìrán Jósẹ́fù wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mósè àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Ísírẹ́lì.
2 Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Ṣélófíhádì arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀.
3 Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Ísírẹ́lì mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbàá kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa.
4 Nígbà tí ọdún Júbélì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ babańlá wọn.”
5 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìrán Jóṣẹ́fù ń ṣọ tọ̀nà.