8 Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lè ní ìpín nínú ogún baba wọn.
9 Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Ísírẹ́lì gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”
10 Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣẹ́lófẹ́hádì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.
11 Nítorí pé a gbé Málà, Tírísà, Hógílà, Mílíkà, àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Ṣélófẹ́hádì ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.
12 Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìrán Mánásè, ọmọ Jóṣẹ́fù ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.
13 Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ tí Olúwa ti ipaṣẹ̀ Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lẹ́bá Jọ́dánì létí Jẹ́ríkò.