14 Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èèlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwo kòtò. Kí wọn ó fi àwọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpo rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
15 “Lẹ́yìn tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀ṣíwájú, kí àwọn ọmọ Kóhátì bọ́ ṣíwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kóhátì ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú Àgọ́ Ìpàdé.
16 “Iṣẹ́ Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àmójútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́.”
17 Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,
18 “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kóhátì kúrò lára àwọn ọmọ Léfì:
19 Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má baà kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálukú àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kóhátì kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”