18 “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kóhátì kúrò lára àwọn ọmọ Léfì:
19 Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má baà kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálukú àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé.
20 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kóhátì kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”
21 Olúwa sọ fún Mósè pé:
22 “Tún ka iye àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.
23 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.
24 “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gáṣónì, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù: