36 Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó dín àádọ́ta (2,750).
37 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kóhátì tó ń ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé; tí Mósè àti Árónì kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.
38 Wọ́n ka àwọn ọmọ Gáṣónì nípa ìdílé àti ile baba wọn.
39 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.
40 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó lé ọgbọ̀n (2,630).
41 Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gásónì, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé. Mósè àti Árónì se bí àṣẹ Olúwa.
42 Wọ́n ka àwọn ọmọ Mérárì nípa ìdílé àti ilé baba wọn.