43 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ Ìpàdé.
44 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200).
45 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Mérárì. Mósè àti Árónì kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.
46 Báyìí ni Mósè, Árónì àti olórí ìjọ ènìyàn ka gbogbo ọmọ Léfì nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
47 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn erù inú Àgọ́ Ìpadé.
48 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580).
49 Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mósè.Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.