6 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìsòótọ́ sí Olúwa, ẹni náà jẹ̀bi.
7 Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn ún rẹ̀ lée, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.
8 Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti Olúwa, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà
9 Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.
10 Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti oun nikan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”
11 Olúwa sọ fún Mósè wí pé,
12 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìsòótọ́ sí i,