12 “Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Léfì bá gbé ọwọ́ wọn lé orí àwọn akọ ọmọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun sí Olúwa, láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Léfì.
13 Mú kí àwọn ọmọ Léfì dúró níwájú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí ó sì gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì sí Olúwa.
14 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe ya ọmọ Léfì sọ́tọ̀, kúrò láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóòkù, àwọn ọmọ Léfì yóò sì jẹ́ tèmi.
15 “Lẹ́yìn tí ó ti wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, tí ó sì ti gbé wọn kalẹ̀ bí ẹbọ fífì nígbà náà ni kí wọn ó lọ máa ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.
16 Nítorí pé àwọn ni ó jẹ́ ti Èmi pátapáta nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo ti gbà wọ́n fún ara mi dípò àwọn àkọ́bí àní àkọ́bí ọkunrin gbogbo Ísírẹ́lì.
17 Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi.
18 Mo sì ti gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Isireli