1 Olúwa sọ fún Mósè nínú ihà Ṣínáì ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì wí pé;
2 “Mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀.
3 Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan-an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”
4 Mósè sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́.