17 Ó sì ṣe, àwọn ológun Júdà tẹ̀lé àwọn ológun Ṣíméónì arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kénánì tí ń gbé Ṣéfátì jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátapáta, ní báyìí à ò pe ìlú náà ní Hómà (Hómà èyí tí ń jẹ́ ìparun).
18 Àwọn ogun Júdà sì ṣẹ́gun Gásà àti àwọn agbègbè rẹ̀, Ásíkélénì àti Ékírónì pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.
19 Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Júdà, wọ́n gba ilẹ̀ òkè ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.
20 Gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti ṣèlérí, wọ́n fún Kélẹ́bù ní Hébírónì ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Ánákì mẹ́ta.
21 Àwọn ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọn kò le lé àwọn Jébúsì tí wọ́n ń gbé Jérúsálẹ́mù nítorí náà wọ́n ń gbé àárin àwọn Ísírẹ́lì títí di òní.
22 Àwọn ẹ̀yà Jóṣẹ́fù sì bá Bẹ́tẹ́lì jagun, Olúwa ṣíwájú pẹ̀lú wọn.
23 Nígbà tí ẹ̀yà Jóṣẹ́fù rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Bẹ́tẹ́lì wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lúsì).