21 “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì fi Síónì àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ísírẹ́lì sì gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí wọ́n ń gbé ní agbégbé náà,
22 wọ́n gbà gbogbo agbégbé àwọn ará Ámórì tí ó fi dé Jábókù, àti láti aṣálẹ̀ dé Jọ́dánì.
23 “Wàyí o, nígbà tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti lé àwọn ará Ámórì kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; Ísírẹ́lì, ẹ̀tọ́ wo ni ẹ ní láti gba ilẹ̀ náà?
24 Ǹjẹ́ ìwọ kì yóò ha gba èyí tí Kémọ́sì òrìṣà rẹ fí fún ọ? Bákan náà àwa yóò gba èyíkéyìí tí Olúwa Ọlọ́run wa fi fún wa.
25 Ǹjẹ́ ìwọ ha sàn jú Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù lọ? Ǹjẹ́ òun ha ṣe gbólóhùn aṣọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì bí? Tàbí òun dojú ìjà kọ wọ́n rí bí?
26 Fún ọ̀ọ́dúnrún ọdún (300) ni Ísírẹ́lì fi ṣe àtìpó ní Hésíbónì, Áróérì àti àwọn ìgbéríko àti àwọn ìlú tí ó yí Ánónì ká. Èéṣe tí ìwọ kò fi gbà wọ́n padà ní àsìkò náà?
27 Èmi kọ́ ni ó ṣẹ̀ ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ ni ó ṣẹ̀ mí nípa kíkógun tọ̀ mí wá. Jẹ́ kí Olúwa olùdájọ́, ṣe ìdájọ́ lónìí láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ará Ámónì.”