6 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́.
7 Ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì kan wà, ẹni tí ó wá láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní Júdà, ẹni tí ó ti ń gbé ní àárin ẹ̀yà Júdà,
8 fi ìlú náà sílẹ̀ láti wá ibòmíràn láti máa gbé. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Míkà nínú àwọn ilẹ̀ òkè Éfúráímù.
9 Míkà bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?”Ó dáhùn pé, “Ọmọ Léfì ni mí láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Júdà, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”
10 Míkà sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi (máa bá mi gbé) kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.”
11 Ọmọ Léfì náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.
12 Nígbà náà ni Míkà ya ará Léfì náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀.