1 Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran túntún ní Ísírẹ́lì wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun, àwọn ará Kénánì.
2 (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Ísírẹ́lì tí kò rí ogun rí ní bí a ti ṣe ń jagun):
3 Àwọn ìjòyè ìlú Fílístínì máràrùn, gbogbo àwọn ará Kénánì, àwọn ará Ṣídónì, àti àwọn ará Hífì tí ń gbé ní àwọn òkè Lébálónì bẹ̀rẹ̀ láti òkè Báálì-Aámónì títí dé Lébò Hámátì.
4 A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Ísírẹ́lì wò bóyá wọn yóò gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipaṣẹ̀ Móṣè.
5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì.
6 Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.
7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa. Wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù.