28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí Olúwa ti fi Móábù ọ̀ta yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jọ́dánì tí ó lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
29 Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Móábù tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.
30 Ní ọjọ́ náà ni Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará Móábù, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.
31 Lẹ́yìn Éhúdù, ni ṣáḿgárì ọmọ Ánátì ẹni tí ó pa ọgọ́rùn ún mẹ́fà Fílístínì pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Ísírẹ́lì kúrò nínú ìpọ́njú.