Onídájọ́ 3:4-10 BMY

4 A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Ísírẹ́lì wò bóyá wọn yóò gbọ́ran sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipaṣẹ̀ Móṣè.

5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì.

6 Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.

7 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa. Wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù.

8 Ìbínú Olúwa sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.

9 Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí Olúwa, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.

10 Ẹ̀mí Olúwa bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. Olúwa sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.