Onídájọ́ 5:25-31 BMY

25 Ó bèèrè omi, ó fún un ní wàrà;ó fi àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́la fún un ni wàrà dídì.

26 Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́,ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà.Ó kan Ṣísérà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òòlù ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ọ ní orí,Ó kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ sinsiǹ.

27 Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ó ṣubú; ó dúbúlẹ̀.Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wó lulẹ̀;ní ibi tí ó gbé wólẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú.

28 “Ìyá Ṣísérà yọjú láti ojú fèrèsé,ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé,‘Èése tí kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé?Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ̀ fí dúró lẹ́yìn?’

29 Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn;àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,

30 ‘Wọn kò ha ti rí wọn, wọn kò ha ti pín ìkógun bọ̀ fún olúkálùkù:ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan,fún Ṣísérà ìkógun aṣọ aláràbarà,ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà,àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi,gbogbo wọn tí a kó ní ogun?’

31 “Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kí ó ṣègbé Olúwa!Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn.nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.”Ilẹ̀ náà sì simi ní ogójì ọdún